Isaiah 5:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀ àti ọmọ ènìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀ ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀.
Isaiah 5:15 in English
Isaiah 5:15 · Berean Standard Bible
So mankind will be brought low, and each man humbled; the arrogant will lower their eyes.
Context
13Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò lọ sí ìgbèkùn
nítorí òye kò sí fún wọn,
ebi ni yóò pa àwọn ọlọ́lá wọn kú;
ẹgbàágbèje wọn ni òǹgbẹ yóò sì gbẹ. 14Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi,
ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada,
nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sí
pẹ̀lú ọlá àti ògo wọn. 15Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀
àti ọmọ ènìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀
ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀. 16Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀,
Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀. 17Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn,
àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.