Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn, àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀.

Isaiah 5:17 in English

Isaiah 5:17 · Berean Standard Bible

Lambs will graze as in their own pastures, and strangers * will feed in the ruins of the wealthy.

Context

15Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀ àti ọmọ ènìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀ ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀. 16Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀, Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀. 17Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn, àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀. 18Ègbé ni fún àwọn tí ń fi ohun asán fa ẹ̀ṣẹ̀, àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹ̀sìn fa ẹsẹ̀, 19sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá, jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè rí i, jẹ́ kí ó súnmọ́ bí jẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Israẹli kí ó dé, kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.