Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá, jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè rí i, jẹ́ kí ó súnmọ́ bí jẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Israẹli kí ó dé, kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.”

Isaiah 5:19 in English

Isaiah 5:19 · Berean Standard Bible

to those who say, “Let Him hurry and hasten His work so that we may see it! Let the plan of the Holy One of Israel come so that we may know it!”

Context

17Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn, àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀. 18Ègbé ni fún àwọn tí ń fi ohun asán fa ẹ̀ṣẹ̀, àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹ̀sìn fa ẹsẹ̀, 19sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá, jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè rí i, jẹ́ kí ó súnmọ́ bí jẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Israẹli kí ó dé, kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.” 20Ègbé ni fún àwọn tí ń pe ibi ní rere, àti rere ní ibi, tí ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn, tí ń fi ìkorò ṣe adùn àti adùn ṣe ìkorò. 21Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn tí wọ́n jáfáfá lójú ara wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.