Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi, ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada, nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sí pẹ̀lú ọlá àti ògo wọn.

Isaiah 5:14 in English

Isaiah 5:14 · Berean Standard Bible

Therefore Sheol enlarges its throat and opens wide its enormous jaws, and down go Zion’s nobles and masses, her revelers and carousers!

Context

12Wọ́n ní dùùrù àti ohun èlò orin olókùn níbi àsè wọn, ṣaworo òun fèrè àti wáìnì, ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí, wọn kò sí bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. 13Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò lọ sí ìgbèkùn nítorí òye kò sí fún wọn, ebi ni yóò pa àwọn ọlọ́lá wọn kú; ẹgbàágbèje wọn ni òǹgbẹ yóò sì gbẹ. 14Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi, ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada, nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sí pẹ̀lú ọlá àti ògo wọn. 15Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀ àti ọmọ ènìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀ ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀. 16Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀, Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.