Isaiah 5:1
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀. Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú.
Isaiah 5:1 in English
Isaiah 5:1 · Berean Standard Bible
I will sing for my beloved a song of his vineyard: My beloved had a vineyard on a very fertile hill.
Context
1Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn
orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀.
Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan
ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú. 2Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò
ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà sí i.
Ó kọ́ ilé ìṣọ́ sí inú rẹ̀
ó sì ṣe ìfúntí kan síbẹ̀ pẹ̀lú.
Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára,
ṣùgbọ́n èso búburú ni ó ti ibẹ̀ wá. 3“Ní ìsinsin yìí ẹ̀yin olùgbé Jerusalẹmu
àti ẹ̀yin ènìyàn Juda
ẹ ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti
ọgbà àjàrà mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.