Isaiah 5:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ìsinsin yìí ẹ̀yin olùgbé Jerusalẹmu àti ẹ̀yin ènìyàn Juda ẹ ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti ọgbà àjàrà mi.
Isaiah 5:3 in English
Isaiah 5:3 · Berean Standard Bible
“And now, O dwellers of Jerusalem and men of Judah, I exhort you to judge between Me and My vineyard.
Context
1Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn
orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀.
Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan
ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú. 2Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò
ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà sí i.
Ó kọ́ ilé ìṣọ́ sí inú rẹ̀
ó sì ṣe ìfúntí kan síbẹ̀ pẹ̀lú.
Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára,
ṣùgbọ́n èso búburú ni ó ti ibẹ̀ wá. 3“Ní ìsinsin yìí ẹ̀yin olùgbé Jerusalẹmu
àti ẹ̀yin ènìyàn Juda
ẹ ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti
ọgbà àjàrà mi. 4Kín ni ó kù tí n ò bá túnṣe sí ọgbà àjàrà mi.
Ju èyí tí mo ti ṣe lọ?
Nígbà tí mo ń wá èso dáradára,
èéṣe tí ó fi so kíkan? 5Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọ
ohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi.
Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò,
a ó sì pa á run,
Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀
yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.