Isaiah 49:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òǹgbẹ kì yóò gbẹ wọ́n, tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí oòrùn kí ó pa wọ́n. Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn, tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi orísun omi.
Isaiah 49:10 in English
Isaiah 49:10 · Berean Standard Bible
They will not hunger or thirst, nor will scorching heat or sun beat down on them.* For He who has compassion on them will guide them and lead them beside springs of water.
Context
8Ohun tí Olúwa wí nìyìí:
“Ní àkókò ojúrere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn,
àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́;
Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́
láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn,
láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò
àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro, 9láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá,’
àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’
“Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nà
àti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko. 10Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òǹgbẹ kì yóò gbẹ wọ́n,
tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí oòrùn kí ó pa wọ́n.
Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn,
tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi orísun omi. 11Èmi yóò sọ gbogbo àwọn òkè ńlá mi di ojú ọ̀nà
àti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé sókè. 12Kíyèsi i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jíjìn
àwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀ láti ìwọ̀-oòrùn,
àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Siene.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.