Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Ní àkókò ojúrere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́; Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro,

Isaiah 49:8 in English

Isaiah 49:8 · Berean Standard Bible

This is what the LORD says: “In the time of favor I will answer You, and in the day of salvation I will help You;* I will keep You and appoint You to be a covenant for the people, to restore the land, to apportion its desolate inheritances,

Context

6Òun wí pé: “Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ mi láti mú ẹ̀yà Jakọbu padà bọ̀ sípò àti láti mú àwọn ti Israẹli tí mo ti pamọ́. Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn kèfèrí, kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wá sí òpin ilẹ̀ ayé.” 7Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Olùdáǹdè àti Ẹni Mímọ́ Israẹli— sí ẹni náà tí a gàn tí a sì kórìíra lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, sí ìránṣẹ́ àwọn aláṣẹ: “Àwọn ọba yóò rí ọ wọn yóò sì dìde sókè, àwọn ọmọ ọba yóò rí i wọn yóò sì wólẹ̀, nítorí Olúwa ẹni tí í ṣe olóòtítọ́, Ẹni Mímọ́ Israẹli tí ó ti yàn ọ́.” 8Ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Ní àkókò ojúrere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́; Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro, 9láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá,’ àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’ “Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nà àti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko. 10Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òǹgbẹ kì yóò gbẹ wọ́n, tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí oòrùn kí ó pa wọ́n. Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn, tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi orísun omi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.