Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Olùdáǹdè àti Ẹni Mímọ́ Israẹli— sí ẹni náà tí a gàn tí a sì kórìíra lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, sí ìránṣẹ́ àwọn aláṣẹ: “Àwọn ọba yóò rí ọ wọn yóò sì dìde sókè, àwọn ọmọ ọba yóò rí i wọn yóò sì wólẹ̀, nítorí Olúwa ẹni tí í ṣe olóòtítọ́, Ẹni Mímọ́ Israẹli tí ó ti yàn ọ́.”

Isaiah 49:7 in English

Isaiah 49:7 · Berean Standard Bible

Thus says the LORD, the Redeemer and Holy One of Israel, to Him who was despised and abhorred by the nation, to the Servant of rulers: “Kings will see You and rise, and princes will bow down, because of the LORD, who is faithful, the Holy One of Israel, who has chosen You.”

Context

5Nísinsin yìí Olúwa wí pé ẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ láti mú Jakọbu padà tọ̀ mí wá àti láti kó Israẹli jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú Olúwa Ọlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi, 6Òun wí pé: “Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ mi láti mú ẹ̀yà Jakọbu padà bọ̀ sípò àti láti mú àwọn ti Israẹli tí mo ti pamọ́. Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn kèfèrí, kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wá sí òpin ilẹ̀ ayé.” 7Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Olùdáǹdè àti Ẹni Mímọ́ Israẹli— sí ẹni náà tí a gàn tí a sì kórìíra lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, sí ìránṣẹ́ àwọn aláṣẹ: “Àwọn ọba yóò rí ọ wọn yóò sì dìde sókè, àwọn ọmọ ọba yóò rí i wọn yóò sì wólẹ̀, nítorí Olúwa ẹni tí í ṣe olóòtítọ́, Ẹni Mímọ́ Israẹli tí ó ti yàn ọ́.” 8Ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Ní àkókò ojúrere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́; Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro, 9láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá,’ àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’ “Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nà àti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.