Isaiah 47:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀síwájú títí láé— ọbabìnrin ayérayé!’ Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi nǹkan wọ̀nyí tàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.
Isaiah 47:7 in English
Isaiah 47:7 · Berean Standard Bible
You said, ‘I will be queen forever.’ You did not take these things to heart or consider their outcome.
Context
5“Jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, lọ sínú òkùnkùn,
ọmọbìnrin àwọn ará Babeli;
a kì yóò pè ọ́ ní ọbabìnrin
àwọn ilẹ̀ ọba mọ́. 6Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mi
tí mo sì ba ogún mi jẹ́,
mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́,
Ìwọ kò sì síjú àánú wò wọ́n.
Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lú
ní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé. 7Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀síwájú títí láé—
ọbabìnrin ayérayé!’
Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi nǹkan wọ̀nyí
tàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀. 8“Nísinsin yìí, tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dá
tí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹ
tí o sì ń sọ fún ara rẹ pé,
‘Èmi ni, kò sì ṣí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.
Èmi kì yóò di opó
tàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’ 9Méjèèjì yìí ni yóò wá sórí rẹ
láìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà:
pípàdánù ọmọ àti dídi opó.
Wọn yóò wá sórí rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,
pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹ
àti àwọn èpè rẹ tí ko lágbára.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.