Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mi tí mo sì ba ogún mi jẹ́, mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì síjú àánú wò wọ́n. Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lú ní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé.

Isaiah 47:6 in English

Isaiah 47:6 · Berean Standard Bible

I was angry with My people; I profaned My heritage, and I placed them under your control. You showed them no mercy; even on the elderly you laid a most heavy yoke.

Context

4Olùràpadà wa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ òun ni Ẹni Mímọ́ Israẹli. 5“Jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, lọ sínú òkùnkùn, ọmọbìnrin àwọn ará Babeli; a kì yóò pè ọ́ ní ọbabìnrin àwọn ilẹ̀ ọba mọ́. 6Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mi tí mo sì ba ogún mi jẹ́, mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì síjú àánú wò wọ́n. Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lú ní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé. 7Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀síwájú títí láé— ọbabìnrin ayérayé!’ Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi nǹkan wọ̀nyí tàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀. 8“Nísinsin yìí, tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dá tí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹ tí o sì ń sọ fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sì ṣí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi. Èmi kì yóò di opó tàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.