Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Méjèèjì yìí ni yóò wá sórí rẹ láìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà: pípàdánù ọmọ àti dídi opó. Wọn yóò wá sórí rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹ àti àwọn èpè rẹ tí ko lágbára.

Isaiah 47:9 in English

Isaiah 47:9 · Berean Standard Bible

These two things will overtake you in a moment, in a single day: loss of children, and widowhood. They will come upon you in full measure, in spite of your many sorceries and the potency of your spells.

Context

7Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀síwájú títí láé— ọbabìnrin ayérayé!’ Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi nǹkan wọ̀nyí tàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀. 8“Nísinsin yìí, tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dá tí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹ tí o sì ń sọ fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sì ṣí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi. Èmi kì yóò di opó tàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’ 9Méjèèjì yìí ni yóò wá sórí rẹ láìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà: pípàdánù ọmọ àti dídi opó. Wọn yóò wá sórí rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹ àti àwọn èpè rẹ tí ko lágbára. 10Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹ ó sì ti wí pé, ‘Kò sí ẹni tí ó rí mi?’ Ọgbọ́n àti òye rẹ ti ṣì ọ́ lọ́nà nígbà tí o wí fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’ 11Ìparun yóò dé bá ọ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò mọ ọ̀nà láti ré e kúrò. Àjálù kan yóò ṣubú lù ọ́ tí o kì yóò le è fi ètùtù ré kúrò; òfò kan tí o kò le faradà ni yóò wá lójijì sí oríì rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.