Isaiah 45:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Nípa ohun tí ó ń bọ̀, ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi, tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?
Isaiah 45:11 in English
Isaiah 45:11 · Berean Standard Bible
Thus says the LORD, the Holy One of Israel, and its Maker: “How dare you question Me about My sons, or instruct Me in the work of My hands?
Context
9“Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà,
ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀.
Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé:
‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’
Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé,
‘Òun kò ní ọwọ́?’ 10Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé,
‘Kí ni o bí?’
tàbí sí ìyá rẹ̀,
‘Kí ni ìwọ ti bí?’ 11“Ohun tí Olúwa wí nìyìí,
Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀.
Nípa ohun tí ó ń bọ̀,
ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi,
tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí? 12Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé
tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀.
Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run;
mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta. 13Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi.
Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.
Òun yóò tún ìlú mi kọ́
yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀,
ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan,
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.