Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi. Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́. Òun yóò tún ìlú mi kọ́ yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

Isaiah 45:13 in English

Isaiah 45:13 · Berean Standard Bible

I will raise up Cyrus in righteousness, and I will make all his ways straight. He will rebuild My city and set My exiles free, but not for payment or reward, says the LORD of Hosts.”

Context

11“Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Nípa ohun tí ó ń bọ̀, ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi, tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí? 12Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀. Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run; mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta. 13Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi. Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́. Òun yóò tún ìlú mi kọ́ yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.” 14Ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Àwọn èròjà ilẹ̀ Ejibiti àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kuṣi, àti àwọn Sabeani— wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ wọn yóò sì jẹ́ tìrẹ; wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn, wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́. Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀, wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé, ‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì ṣí ẹlòmíràn; kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ” 15Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́, Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Israẹli,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.