Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé, ‘Kí ni o bí?’ tàbí sí ìyá rẹ̀, ‘Kí ni ìwọ ti bí?’

Isaiah 45:10 in English

Isaiah 45:10 · Berean Standard Bible

Woe to him who says to his father, ‘What have you begotten?’ or to his mother, ‘What have you brought forth?’”

Context

8“Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀; jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀. Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada, jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè, jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀; Èmi Olúwa ni ó ti dá a. 9“Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà, ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀. Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé: ‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’ Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé, ‘Òun kò ní ọwọ́?’ 10Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé, ‘Kí ni o bí?’ tàbí sí ìyá rẹ̀, ‘Kí ni ìwọ ti bí?’ 11“Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Nípa ohun tí ó ń bọ̀, ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi, tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí? 12Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀. Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run; mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.