Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀; jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀. Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada, jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè, jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀; Èmi Olúwa ni ó ti dá a.

Isaiah 45:8 in English

Isaiah 45:8 · Berean Standard Bible

Drip down, O heavens, from above, and let the skies pour down righteousness. Let the earth open up that salvation may sprout and righteousness spring up with it; I, the LORD, have created it.

Context

6tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀ kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi. Èmi ni Olúwa, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́. 7Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn, Mo mú àlàáfíà wá, Mo sì dá àjálù; Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí. 8“Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀; jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀. Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada, jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè, jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀; Èmi Olúwa ni ó ti dá a. 9“Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà, ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀. Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé: ‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’ Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé, ‘Òun kò ní ọwọ́?’ 10Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé, ‘Kí ni o bí?’ tàbí sí ìyá rẹ̀, ‘Kí ni ìwọ ti bí?’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.