Isaiah 45:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn, Mo mú àlàáfíà wá, Mo sì dá àjálù; Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.
Isaiah 45:7 in English
Isaiah 45:7 · Berean Standard Bible
I form the light and create the darkness; I bring prosperity and create calamity. I, the LORD, do all these things.
Context
5Èmi ni Olúwa, àti pé kò sí ẹlòmíràn;
yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan,
Èmi yóò fún ọ ní okun,
bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí, 6tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn
títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀
kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi.
Èmi ni Olúwa, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́. 7Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn,
Mo mú àlàáfíà wá, Mo sì dá àjálù;
Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí. 8“Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀;
jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀.
Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada,
jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè,
jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀;
Èmi Olúwa ni ó ti dá a. 9“Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà,
ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀.
Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé:
‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’
Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé,
‘Òun kò ní ọwọ́?’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.