Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi ni Olúwa, àti pé kò sí ẹlòmíràn; yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan, Èmi yóò fún ọ ní okun, bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí,

Isaiah 45:5 in English

Isaiah 45:5 · Berean Standard Bible

I am the LORD, and there is no other; there is no God but Me. I will equip you for battle, though you have not known Me,

Context

3Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn, ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin, tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ. 4Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ mi àti Israẹli ẹni tí mo yàn, Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ, mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí. 5Èmi ni Olúwa, àti pé kò sí ẹlòmíràn; yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan, Èmi yóò fún ọ ní okun, bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí, 6tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀ kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi. Èmi ni Olúwa, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́. 7Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn, Mo mú àlàáfíà wá, Mo sì dá àjálù; Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.