Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère, tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?

Isaiah 44:10 in English

Isaiah 44:10 · Berean Standard Bible

Who fashions a god or casts an idol which profits him nothing?

Context

8Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù. Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tipẹ́tipẹ́? Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ha ń bẹ lẹ́yìn mi? Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.” 9Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán, àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́ kò jámọ́ nǹkan kan. Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú; wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan sí ìtìjú ara wọn. 10Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère, tí kò lè mú èrè kankan wá fún un? 11Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójútì; àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n. Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sì fi ìdúró wọn hàn; gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú ìpayà àti àbùkù. 12Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò, ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú; ó fi òòlù ya ère kan, ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀, ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un; kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.