Isaiah 44:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò, ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú; ó fi òòlù ya ère kan, ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀, ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un; kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a.
Isaiah 44:12 in English
Isaiah 44:12 · Berean Standard Bible
The blacksmith takes a tool and labors over the coals; he fashions an idol with hammers and forges it with his strong arms. Yet he grows hungry and loses his strength; he fails to drink water and grows faint.
Context
10Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère,
tí kò lè mú èrè kankan wá fún un? 11Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójútì;
àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n.
Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sì
fi ìdúró wọn hàn;
gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú ìpayà àti àbùkù. 12Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò,
ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú;
ó fi òòlù ya ère kan,
ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀,
ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un;
kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a. 13Gbẹ́nàgbẹ́nà fi ìwọ̀n wọ́n ọ́n
ó sì fi lẹ́ẹ̀dì ṣe àmì sí ara rẹ̀,
Ó tún fi ìfà fá a jáde
ó tún fi òsùwọ̀n ṣe àmì sí i.
Ó gbẹ́ ẹ ní ìrí ènìyàn
gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nínú ògo rẹ̀,
kí ó lè máa gbé nínú ilé òrìṣà. 14Ó gé igi kedari lulẹ̀,
tàbí bóyá ó mú sípírẹ́ṣì tàbí igi óákù.
Ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrín àwọn igi inú igbó,
ó sì le gbin igi páínì, èyí tí òjò mú kí ó dàgbà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.