Isaiah 44:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù. Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tipẹ́tipẹ́? Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ha ń bẹ lẹ́yìn mi? Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.”
Isaiah 44:8 in English
Isaiah 44:8 · Berean Standard Bible
Do not tremble or fear. Have I not told you and declared it long ago? You are My witnesses! Is there any God but Me? There is no other Rock; I know not one.”
Context
6“Ohun tí Olúwa wí nìyìí
ọba Israẹli àti Olùdáǹdè, àní
Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn,
lẹ́yìn mi kò sí Ọlọ́run kan. 7Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀.
Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú mi
kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdí àwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀,
àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá. 8Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù.
Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọ
àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tipẹ́tipẹ́?
Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan
ha ń bẹ lẹ́yìn mi?
Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.” 9Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán,
àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́
kò jámọ́ nǹkan kan.
Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú;
wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan sí ìtìjú ara wọn. 10Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère,
tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.