Isaiah 44:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ohun tí Olúwa wí nìyìí ọba Israẹli àti Olùdáǹdè, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn, lẹ́yìn mi kò sí Ọlọ́run kan.
Isaiah 44:6 in English
Isaiah 44:6 · Berean Standard Bible
Thus says the LORD, the King and Redeemer of Israel, the LORD of Hosts: “I am the first and I am the last, and there is no God but Me.
Context
4Wọn yóò dàgbàsókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínú pápá oko tútù,
àti gẹ́gẹ́ bí igi Poplari létí odò tí ń sàn. 5Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti Olúwa’;
òmíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jakọbu;
bẹ́ẹ̀ ni òmíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, ‘Ti Olúwa,’
yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Israẹli. 6“Ohun tí Olúwa wí nìyìí
ọba Israẹli àti Olùdáǹdè, àní
Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn,
lẹ́yìn mi kò sí Ọlọ́run kan. 7Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀.
Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú mi
kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdí àwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀,
àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá. 8Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù.
Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọ
àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tipẹ́tipẹ́?
Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan
ha ń bẹ lẹ́yìn mi?
Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.