Isaiah 43:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kéde Èmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrín yín. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí, “Pé Èmi ni Ọlọ́run.
Isaiah 43:12 in English
Isaiah 43:12 · Berean Standard Bible
I alone decreed and saved and proclaimed— I, and not some foreign god among you. So you are My witnesses,” declares the LORD, “that I am God.
Context
10“Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí,
“Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn,
tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà mí gbọ́
tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà.
Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá,
tàbí a ó wa rí òmíràn lẹ́yìn mi. 11Èmi, àní Èmi, Èmi ni Olúwa,
yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn. 12Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kéde
Èmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrín yín.
Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí, “Pé Èmi ni Ọlọ́run. 13Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà.
Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi.
Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?” 14Èyí ni ohun tí Olúwa wí,
olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli:
“Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Babeli
láti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá, gbogbo ará Babeli,
nínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.