Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi, àní Èmi, Èmi ni Olúwa, yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn.

Isaiah 43:11 in English

Isaiah 43:11 · Berean Standard Bible

I, yes I, am the LORD, and there is no Savior but Me.

Context

9Gbogbo orílẹ̀-èdè kó ra wọn jọ àwọn ènìyàn sì kó ra wọn papọ̀. Ta ni nínú wọn tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí tí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀? Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wá láti fihàn pé wọ́n tọ̀nà tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́, tí wọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.” 10“Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí, “Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà mí gbọ́ tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà. Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá, tàbí a ó wa rí òmíràn lẹ́yìn mi. 11Èmi, àní Èmi, Èmi ni Olúwa, yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn. 12Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kéde Èmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrín yín. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí, “Pé Èmi ni Ọlọ́run. 13Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.