Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ta ni ó fi Jakọbu lélẹ̀ fún ìkógun, àti Israẹli sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí? Kì í ha ṣe Olúwa ni, ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí? Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀; wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ.

Isaiah 42:24 in English

Isaiah 42:24 · Berean Standard Bible

Who gave Jacob up for spoil, and Israel to the plunderers? Was it not the LORD, against whom we have sinned? They were unwilling to walk in His ways, and they would not obey His law.

Context

22Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan nìyìí tí a jà lógun tí a sì kó lẹ́rú, gbogbo wọn ni ó wà nínú ọ̀gbun, tàbí tí a fi pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n. Wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹnìkan tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀; wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹni tí yóò sọ pé, “Dá wọn padà.” 23Ta ni nínú yín tí yóò tẹ́tí sí èyí tàbí kí ó ṣe àkíyèsí gidi ní àsìkò tí ó ń bọ̀? 24Ta ni ó fi Jakọbu lélẹ̀ fún ìkógun, àti Israẹli sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí? Kì í ha ṣe Olúwa ni, ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí? Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀; wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ. 25Nítorí náà ni ó ṣe rọ̀jò ìbínú un rẹ̀ lé wọn lórí, rògbòdìyàn ogun. Èyí tí ó fi ahọ́n iná yí wọn po, síbẹ̀ èdè kò yé wọn; ó jó wọn run, síbẹ̀ wọn kò fi sọ́kàn wọn rárá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.