Isaiah 42:25
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà ni ó ṣe rọ̀jò ìbínú un rẹ̀ lé wọn lórí, rògbòdìyàn ogun. Èyí tí ó fi ahọ́n iná yí wọn po, síbẹ̀ èdè kò yé wọn; ó jó wọn run, síbẹ̀ wọn kò fi sọ́kàn wọn rárá.
Isaiah 42:25 in English
Isaiah 42:25 · Berean Standard Bible
So He poured out on them His furious anger and the fierceness of battle. It enveloped them in flames, but they did not understand; it consumed them, but they did not take it to heart.
Context
23Ta ni nínú yín tí yóò tẹ́tí sí èyí
tàbí kí ó ṣe àkíyèsí gidi ní àsìkò tí ó ń bọ̀? 24Ta ni ó fi Jakọbu lélẹ̀ fún ìkógun,
àti Israẹli sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí?
Kì í ha ṣe Olúwa ni,
ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí?
Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀;
wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ. 25Nítorí náà ni ó ṣe rọ̀jò ìbínú un rẹ̀ lé wọn lórí,
rògbòdìyàn ogun.
Èyí tí ó fi ahọ́n iná yí wọn po, síbẹ̀ èdè kò yé wọn;
ó jó wọn run, síbẹ̀ wọn kò fi sọ́kàn wọn rárá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.