Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan nìyìí tí a jà lógun tí a sì kó lẹ́rú, gbogbo wọn ni ó wà nínú ọ̀gbun, tàbí tí a fi pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n. Wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹnìkan tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀; wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹni tí yóò sọ pé, “Dá wọn padà.”

Isaiah 42:22 in English

Isaiah 42:22 · Berean Standard Bible

But this is a people plundered and looted, all trapped in caves or imprisoned in dungeons. They have become plunder with no one to rescue them, and loot with no one to say, “Send them back!”

Context

20Ẹ̀yin ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, ṣùgbọ́n ẹ kò ṣe àkíyèsí; etí yín yà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́ nǹkan kan.” 21Ó dùn mọ́ Olúwa nítorí òdodo rẹ̀ láti mú òfin rẹ lágbára àti ògo. 22Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan nìyìí tí a jà lógun tí a sì kó lẹ́rú, gbogbo wọn ni ó wà nínú ọ̀gbun, tàbí tí a fi pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n. Wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹnìkan tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀; wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹni tí yóò sọ pé, “Dá wọn padà.” 23Ta ni nínú yín tí yóò tẹ́tí sí èyí tàbí kí ó ṣe àkíyèsí gidi ní àsìkò tí ó ń bọ̀? 24Ta ni ó fi Jakọbu lélẹ̀ fún ìkógun, àti Israẹli sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí? Kì í ha ṣe Olúwa ni, ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí? Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀; wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.