Isaiah 42:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, ṣùgbọ́n ẹ kò ṣe àkíyèsí; etí yín yà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́ nǹkan kan.”
Isaiah 42:20 in English
Isaiah 42:20 · Berean Standard Bible
Though seeing many things, you do not keep watch. Though your ears are open, you do not hear.”
Context
18“Gbọ́, ìwọ adití,
wò ó, ìwọ afọ́jú, o sì rí! 19Ta ló fọ́jú bí kò ṣe ìránṣẹ́ mi,
àti odi gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí mo rán?
Ta ni ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fi jìnmí,
ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Olúwa? 20Ẹ̀yin ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, ṣùgbọ́n ẹ kò ṣe àkíyèsí;
etí yín yà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́ nǹkan kan.” 21Ó dùn mọ́ Olúwa
nítorí òdodo rẹ̀
láti mú òfin rẹ lágbára àti ògo. 22Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan nìyìí tí a jà lógun
tí a sì kó lẹ́rú,
gbogbo wọn ni ó wà nínú ọ̀gbun,
tàbí tí a fi pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n.
Wọ́n ti di ìkógun,
láìsí ẹnìkan tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀;
wọ́n ti di ìkógun,
láìsí ẹni tí yóò sọ pé, “Dá wọn padà.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.