Isaiah 41:23
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ẹ sọ fún wa ohun ti ọjọ́ iwájú mú dání kí àwa kí ó lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín. Ẹ ṣe nǹkan kan, ìbá à ṣe rere tàbí búburú, tó bẹ́ẹ̀ tí àyà yóò fi fò wá tí ẹ̀rù yóò sì fi kún inú wa.
Isaiah 41:23 in English
Isaiah 41:23 · Berean Standard Bible
Tell us the things that are to come, so that we may know that you are gods. Yes, do something good or evil, that we may look on together in dismay.
Context
21“Mú ẹjọ́ wá,” ni Olúwa wí.
“Tẹ́ àwọn àwíjàre rẹ sílẹ̀,” ni ọba Jakọbu wí, 22“Mú àwọn ère òrìṣà rẹ wọlé láti sọ fún wa
ohun tí yóò ṣẹlẹ̀.
Sọ fún wa ohun tí àwọn nǹkan àtijọ́ jẹ́,
kí àwa lè ṣe àgbéyẹ̀wò wọn
kí àwa sì mọ àbájáde wọn ní ìparí.
Tàbí kí o sọ fún wa ohun tí ó ń bọ̀ wá, 23ẹ sọ fún wa ohun ti ọjọ́ iwájú mú dání
kí àwa kí ó lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín.
Ẹ ṣe nǹkan kan, ìbá à ṣe rere tàbí búburú,
tó bẹ́ẹ̀ tí àyà yóò fi fò wá tí ẹ̀rù yóò sì fi kún inú wa. 24Ṣùgbọ́n ẹ̀yìn ko jásí nǹkan kan
iṣẹ́ yín ni kò sì wúlò fún ohunkóhun;
ẹni tí ó yàn yín jẹ́ ẹni ìríra. 25“Èmi ti ru ẹnìkan sókè láti àríwá, òun sì ń bọ
ẹnìkan láti ìlà-oòrùn tí ó pe orúkọ mi.
Òun gun àwọn aláṣẹ mọ́lẹ̀ bí ẹni pé odò ni wọ́n,
àfi bí ẹni pé amọ̀kòkò nì ti ń gún amọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.