Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ẹ̀yìn ko jásí nǹkan kan iṣẹ́ yín ni kò sì wúlò fún ohunkóhun; ẹni tí ó yàn yín jẹ́ ẹni ìríra.

Isaiah 41:24 in English

Isaiah 41:24 · Berean Standard Bible

Behold, you are nothing and your work is of no value. Anyone who chooses you is detestable.

Context

22“Mú àwọn ère òrìṣà rẹ wọlé láti sọ fún wa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Sọ fún wa ohun tí àwọn nǹkan àtijọ́ jẹ́, kí àwa lè ṣe àgbéyẹ̀wò wọn kí àwa sì mọ àbájáde wọn ní ìparí. Tàbí kí o sọ fún wa ohun tí ó ń bọ̀ wá, 23ẹ sọ fún wa ohun ti ọjọ́ iwájú mú dání kí àwa kí ó lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín. Ẹ ṣe nǹkan kan, ìbá à ṣe rere tàbí búburú, tó bẹ́ẹ̀ tí àyà yóò fi fò wá tí ẹ̀rù yóò sì fi kún inú wa. 24Ṣùgbọ́n ẹ̀yìn ko jásí nǹkan kan iṣẹ́ yín ni kò sì wúlò fún ohunkóhun; ẹni tí ó yàn yín jẹ́ ẹni ìríra. 25“Èmi ti ru ẹnìkan sókè láti àríwá, òun sì ń bọ ẹnìkan láti ìlà-oòrùn tí ó pe orúkọ mi. Òun gun àwọn aláṣẹ mọ́lẹ̀ bí ẹni pé odò ni wọ́n, àfi bí ẹni pé amọ̀kòkò nì ti ń gún amọ̀. 26Ta ni ó sọ èyí láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, tí àwa kò bá fi mọ̀, tàbí ṣáájú àkókò, tí àwa kò bá fi wí pé, ‘Òun sọ òtítọ́’? Ẹnikẹ́ni kò sọ nípa èyí, ẹnikẹ́ni kò sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.