Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èéṣe tí o fi sọ, ìwọ Jakọbu? Àti tí o ṣàròyé, ìwọ Israẹli, “Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú Olúwa; ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí láti ọwọ́ Ọlọ́run mi”?

Isaiah 40:27 in English

Isaiah 40:27 · Berean Standard Bible

Why do you say, O Jacob, and why do you assert, O Israel, “My way is hidden from the LORD, and my claim is ignored by my God”?

Context

25“Ta ni ẹ ó fi mi wé? Tàbí ta ni ó bá mi dọ́gba?” ni Ẹni Mímọ́ wí. 26Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wo àwọn ọ̀run. Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí? Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan tí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan. Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀, ọ̀kan ṣoṣo nínú wọn kò sọnù. 27Èéṣe tí o fi sọ, ìwọ Jakọbu? Àti tí o ṣàròyé, ìwọ Israẹli, “Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú Olúwa; ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí láti ọwọ́ Ọlọ́run mi”? 28Ìwọ kò tí ì mọ̀? Ìwọ kò tí ì gbọ́? Olúwa òun ni Ọlọ́run ayérayé, Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé. Agara kì yóò da bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣàárẹ̀, àti òye rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdínwọ̀n rẹ̀. 29Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀ ó sì fi kún agbára àwọn tí agara dá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.