Isaiah 40:25
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ta ni ẹ ó fi mi wé? Tàbí ta ni ó bá mi dọ́gba?” ni Ẹni Mímọ́ wí.
Isaiah 40:25 in English
Isaiah 40:25 · Berean Standard Bible
“To whom will you liken Me, or who is My equal?” asks the Holy One.
Context
23Ó sọ àwọn ọmọ ọba di asán
àti àwọn aláṣẹ ayé yìí ni ó ti sọ dòfo. 24Gẹ́rẹ́ tí a ti gbìn wọ́n,
kété tí a gbìn wọ́n,
kété tí wọ́n fi gbòǹgbò múlẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ó fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n gbogbo wọn sì gbẹ,
bẹ́ ni ìjì líle sì gbá wọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò. 25“Ta ni ẹ ó fi mi wé?
Tàbí ta ni ó bá mi dọ́gba?” ni Ẹni Mímọ́ wí. 26Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wo àwọn ọ̀run.
Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí?
Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan
tí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan.
Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀,
ọ̀kan ṣoṣo nínú wọn kò sọnù. 27Èéṣe tí o fi sọ, ìwọ Jakọbu?
Àti tí o ṣàròyé, ìwọ Israẹli,
“Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú Olúwa;
ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí láti ọwọ́ Ọlọ́run mi”?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.