Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀gún yóò sì hù jáde nínú àwọn ààfin rẹ̀ wọ̀nyí, ẹ̀gún ọ̀gán nínú ìlú olódi rẹ̀. Yóò jẹ́ ibùgbé àwọn akátá àti àgbàlá fún àwọn òwìwí.

Isaiah 34:13 in English

Isaiah 34:13 · Berean Standard Bible

Her towers will be overgrown with thorns, her fortresses with thistles and briers. She will become a haunt for jackals,* an abode for ostriches.*

Context

11Òwìwí aginjù, àti àkàlà ni yóò ni ín, àti òwìwí àti ẹyẹ ìwò ni yóò máa gbé inú rẹ̀. Ọlọ́run yóò sì na sórí Edomu okùn ìwọ̀n ìparun àti òkúta òfo. 12Ní ti àwọn ìjòyè rẹ̀ ẹnìkan kì yóò sí níbẹ̀ tiwọn ó pè wá sí ìjọba, gbogbo àwọn olórí i rẹ̀ yóò sì di asán. 13Ẹ̀gún yóò sì hù jáde nínú àwọn ààfin rẹ̀ wọ̀nyí, ẹ̀gún ọ̀gán nínú ìlú olódi rẹ̀. Yóò jẹ́ ibùgbé àwọn akátá àti àgbàlá fún àwọn òwìwí. 14Àwọn ẹranko ijù àti àwọn ìkookò ni yóò pàdé, àti ewúrẹ́ igbó kan yóò máa kọ sí èkejì rẹ̀, iwin yóò máa gbé ibẹ̀ pẹ̀lú, yóò sì rí ibi ìsinmi fún ara rẹ̀. 15Òwìwí yóò tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ síbẹ̀, yóò yé, yóò sì pa, yóò sì kójọ lábẹ́ òjìji rẹ̀: àwọn gúnnugún yóò péjọ síbẹ̀ pẹ̀lú, olúkúlùkù pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.