Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ti àwọn ìjòyè rẹ̀ ẹnìkan kì yóò sí níbẹ̀ tiwọn ó pè wá sí ìjọba, gbogbo àwọn olórí i rẹ̀ yóò sì di asán.

Isaiah 34:12 in English

Isaiah 34:12 · Berean Standard Bible

No nobles will be left to proclaim a king, and all her princes will come to nothing.

Context

10A kì yóò pa á ní òru tàbí ní ọ̀sán; èéfín rẹ̀ yóò gòkè láéláé: yóò dahoro láti ìran dé ìran, kò sí ẹnìkan tí yóò là á kọjá láé àti láéláé. 11Òwìwí aginjù, àti àkàlà ni yóò ni ín, àti òwìwí àti ẹyẹ ìwò ni yóò máa gbé inú rẹ̀. Ọlọ́run yóò sì na sórí Edomu okùn ìwọ̀n ìparun àti òkúta òfo. 12Ní ti àwọn ìjòyè rẹ̀ ẹnìkan kì yóò sí níbẹ̀ tiwọn ó pè wá sí ìjọba, gbogbo àwọn olórí i rẹ̀ yóò sì di asán. 13Ẹ̀gún yóò sì hù jáde nínú àwọn ààfin rẹ̀ wọ̀nyí, ẹ̀gún ọ̀gán nínú ìlú olódi rẹ̀. Yóò jẹ́ ibùgbé àwọn akátá àti àgbàlá fún àwọn òwìwí. 14Àwọn ẹranko ijù àti àwọn ìkookò ni yóò pàdé, àti ewúrẹ́ igbó kan yóò máa kọ sí èkejì rẹ̀, iwin yóò máa gbé ibẹ̀ pẹ̀lú, yóò sì rí ibi ìsinmi fún ara rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.