Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ẹranko ijù àti àwọn ìkookò ni yóò pàdé, àti ewúrẹ́ igbó kan yóò máa kọ sí èkejì rẹ̀, iwin yóò máa gbé ibẹ̀ pẹ̀lú, yóò sì rí ibi ìsinmi fún ara rẹ̀.

Isaiah 34:14 in English

Isaiah 34:14 · Berean Standard Bible

The desert creatures will meet with hyenas, and one wild goat will call to another. There the night creature * will settle and find her place of repose.

Context

12Ní ti àwọn ìjòyè rẹ̀ ẹnìkan kì yóò sí níbẹ̀ tiwọn ó pè wá sí ìjọba, gbogbo àwọn olórí i rẹ̀ yóò sì di asán. 13Ẹ̀gún yóò sì hù jáde nínú àwọn ààfin rẹ̀ wọ̀nyí, ẹ̀gún ọ̀gán nínú ìlú olódi rẹ̀. Yóò jẹ́ ibùgbé àwọn akátá àti àgbàlá fún àwọn òwìwí. 14Àwọn ẹranko ijù àti àwọn ìkookò ni yóò pàdé, àti ewúrẹ́ igbó kan yóò máa kọ sí èkejì rẹ̀, iwin yóò máa gbé ibẹ̀ pẹ̀lú, yóò sì rí ibi ìsinmi fún ara rẹ̀. 15Òwìwí yóò tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ síbẹ̀, yóò yé, yóò sì pa, yóò sì kójọ lábẹ́ òjìji rẹ̀: àwọn gúnnugún yóò péjọ síbẹ̀ pẹ̀lú, olúkúlùkù pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀. 16Ẹ wo ìwé Olúwa, kí ẹ sì kà. Ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí kì yóò yẹ̀, kò sí ọ̀kan tí yóò fẹ́ èkejì rẹ̀ kù: nítorí Olúwa ti pàṣẹ ẹnu rẹ̀ ló sì fi kó wọn jọ Ẹ̀mí rẹ̀ ló sì fi tò wọ́n jọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.