Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ wo ìwé Olúwa, kí ẹ sì kà. Ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí kì yóò yẹ̀, kò sí ọ̀kan tí yóò fẹ́ èkejì rẹ̀ kù: nítorí Olúwa ti pàṣẹ ẹnu rẹ̀ ló sì fi kó wọn jọ Ẹ̀mí rẹ̀ ló sì fi tò wọ́n jọ.

Isaiah 34:16 in English

Isaiah 34:16 · Berean Standard Bible

Search and read the scroll of the LORD: Not one of these will go missing, not one will lack her mate, because He has ordered it by His mouth, and He will gather them by His Spirit.

Context

14Àwọn ẹranko ijù àti àwọn ìkookò ni yóò pàdé, àti ewúrẹ́ igbó kan yóò máa kọ sí èkejì rẹ̀, iwin yóò máa gbé ibẹ̀ pẹ̀lú, yóò sì rí ibi ìsinmi fún ara rẹ̀. 15Òwìwí yóò tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ síbẹ̀, yóò yé, yóò sì pa, yóò sì kójọ lábẹ́ òjìji rẹ̀: àwọn gúnnugún yóò péjọ síbẹ̀ pẹ̀lú, olúkúlùkù pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀. 16Ẹ wo ìwé Olúwa, kí ẹ sì kà. Ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí kì yóò yẹ̀, kò sí ọ̀kan tí yóò fẹ́ èkejì rẹ̀ kù: nítorí Olúwa ti pàṣẹ ẹnu rẹ̀ ló sì fi kó wọn jọ Ẹ̀mí rẹ̀ ló sì fi tò wọ́n jọ. 17Ó ti di ìbò fún wọn, ọwọ́ rẹ̀ sì ti pín in fún wọn nípa títa okùn, wọn ó jogún rẹ̀ láéláé, láti ìran dé ìran ni wọn ó máa gbé inú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.