Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀rù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Sioni; ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́: “Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun? Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná àìnípẹ̀kun?”

Isaiah 33:14 in English

Isaiah 33:14 · Berean Standard Bible

The sinners in Zion are afraid; trembling grips the ungodly: “Who of us can dwell with a consuming fire? Who of us can dwell with everlasting flames?”

Context

12A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú; bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.” 13Ìwọ tí ó wà lọ́nà jíjìn, gbọ́ ohun tí mo ti ṣe; ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi! 14Ẹ̀rù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Sioni; ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́: “Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun? Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná àìnípẹ̀kun?” 15Ẹni tí ó ń rìn lódodo tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́, tí ó kọ èrè tí ó ti ibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ó di etí rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn tí ó sì di ojú rẹ̀ sí à ti pète ibi, 16Òun náà yóò gbé ní ibi gíga, ibi ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi. A ó mú oúnjẹ fún un, omi rẹ̀ yóò sì dájú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.