Isaiah 33:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ tí ó wà lọ́nà jíjìn, gbọ́ ohun tí mo ti ṣe; ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!
Isaiah 33:13 in English
Isaiah 33:13 · Berean Standard Bible
You who are far off, hear what I have done; you who are near, acknowledge My might.”
Context
11Ìwọ lóyún ìyàngbò,
o sì bí koríko;
èémí yín bí iná tí yóò jẹ yín run. 12A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú;
bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.” 13Ìwọ tí ó wà lọ́nà jíjìn, gbọ́ ohun tí mo ti ṣe;
ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi! 14Ẹ̀rù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Sioni;
ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́:
“Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun?
Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná àìnípẹ̀kun?” 15Ẹni tí ó ń rìn lódodo
tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́,
tí ó kọ èrè tí ó ti ibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá,
tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
tí ó di etí rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn
tí ó sì di ojú rẹ̀ sí à ti pète ibi,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.