Isaiah 33:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ìsinsin yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí. “Ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi ga, ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi sókè.
Isaiah 33:10 in English
Isaiah 33:10 · Berean Standard Bible
“Now I will arise,” says the LORD. “Now I will lift Myself up. Now I will be exalted.
Context
8Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣá tì,
kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nà.
A ti ba àdéhùn jẹ́,
a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí,
a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni. 9Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù,
ojú ti Lebanoni ó sì sá
Ṣaroni sì dàbí aginjù,
àti Baṣani òun Karmeli rẹ àwọn èwe wọn. 10“Ní ìsinsin yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí.
“Ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi ga,
ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi sókè. 11Ìwọ lóyún ìyàngbò,
o sì bí koríko;
èémí yín bí iná tí yóò jẹ yín run. 12A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú;
bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.