Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣá tì, kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nà. A ti ba àdéhùn jẹ́, a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí, a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni.

Isaiah 33:8 in English

Isaiah 33:8 · Berean Standard Bible

The highways are deserted; travel has ceased. The treaty * has been broken, the witnesses * are despised, and human life is disregarded.

Context

6Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹ ibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀; ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí. 7Wò ó, àwọn onígboyà ọkùnrin wọn pohùnréré ẹkún ní òpópónà; àwọn ikọ̀ àlàáfíà sọkún kíkorò. 8Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣá tì, kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nà. A ti ba àdéhùn jẹ́, a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí, a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni. 9Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù, ojú ti Lebanoni ó sì sá Ṣaroni sì dàbí aginjù, àti Baṣani òun Karmeli rẹ àwọn èwe wọn. 10“Ní ìsinsin yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí. “Ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi ga, ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi sókè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.