Isaiah 32:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ti gba ìtẹ́lọ́rùn gidi ẹ dìde kí ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ọkàn yín ti balẹ̀, ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ!
Isaiah 32:9 in English
Isaiah 32:9 · Berean Standard Bible
Stand up, you complacent women; listen to me. Give ear to my word, you overconfident daughters.
Context
7Ibi ni gbogbo ọgbọ́n àwọn ìkà ènìyàn jẹ́,
ó ń gba èrò búburú
láti fi ọ̀rọ̀ èké pa tálákà run,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ aláìní sì tọ̀nà. 8Ṣùgbọ́n ọlọ́lá ènìyàn a máa pète ohun ńlá
àti nípa èrò rere ni yóò dúró. 9Ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ti gba ìtẹ́lọ́rùn gidi
ẹ dìde kí ẹ tẹ́tí sí mi,
ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ọkàn yín ti balẹ̀,
ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ! 10Ní ó lé díẹ̀ ní ọdún kan
ẹ̀yin tí ọkàn an yín balẹ̀ yóò wárìrì;
ìkórè àjàrà kò ní múnádóko,
bẹ́ẹ̀ ni ìkórè èso kò ní sí. 11Wárìrì, ẹ̀yin obìnrin onítẹ̀lọ́rùn;
bẹ̀rù, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ẹ rò pé ọkàn yín balẹ̀!
Ẹ bọ́ aṣọ yín kúrò,
ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.