Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ọlọ́lá ènìyàn a máa pète ohun ńlá àti nípa èrò rere ni yóò dúró.

Isaiah 32:8 in English

Isaiah 32:8 · Berean Standard Bible

But a noble man makes honorable plans; he stands up for worthy causes.

Context

6Nítorí òmùgọ̀ sọ̀rọ̀ òmùgọ̀, ọkàn rẹ̀ kún fún ìwà ibi: òun hùwà àìwà-bí-Ọlọ́run ó sì ń tan àṣìṣe tí ó kan Olúwa kalẹ̀; ẹni ebi ń pa ló fi sílẹ̀ lófo àti fún àwọn tí òǹgbẹ ń gbẹ ni ó mú omi kúrò. 7Ibi ni gbogbo ọgbọ́n àwọn ìkà ènìyàn jẹ́, ó ń gba èrò búburú láti fi ọ̀rọ̀ èké pa tálákà run, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ aláìní sì tọ̀nà. 8Ṣùgbọ́n ọlọ́lá ènìyàn a máa pète ohun ńlá àti nípa èrò rere ni yóò dúró. 9Ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ti gba ìtẹ́lọ́rùn gidi ẹ dìde kí ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ọkàn yín ti balẹ̀, ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ! 10Ní ó lé díẹ̀ ní ọdún kan ẹ̀yin tí ọkàn an yín balẹ̀ yóò wárìrì; ìkórè àjàrà kò ní múnádóko, bẹ́ẹ̀ ni ìkórè èso kò ní sí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.