Isaiah 31:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.
Isaiah 31:6 in English
Isaiah 31:6 · Berean Standard Bible
Return to the One against whom you have so blatantly rebelled, O children of Israel.
Context
4Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:
“Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í ké
àní kìnnìún ńlá lórí ẹran ọdẹ rẹ̀
bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn
tí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojú rẹ̀,
ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọn
akitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wá
láti jagun lórí òkè Sioni àti lórí ibi gíga rẹ̀. 5Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè
Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bo Jerusalẹmu,
Òun yóò dáàbò bò ó, yóò sì tú u sílẹ̀
Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.” 6Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. 7Nítorí ní ọjọ́ náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò kọ àwọn ère fàdákà àti wúrà tí ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín ti ṣe. 8“Asiria yóò ṣubú lọ́wọ́ idà kan tí kò ti ọwọ́ ènìyàn wá;
idà tí kì í ṣe ti ẹ̀dá alààyè ni yóò pa wọ́n.
Wọn yóò sì sá níwájú idà náà
àti àwọn ọmọkùnrin wọn ni a ó fún ní iṣẹ́ ipá ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.