Isaiah 31:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bo Jerusalẹmu, Òun yóò dáàbò bò ó, yóò sì tú u sílẹ̀ Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.”
Isaiah 31:5 in English
Isaiah 31:5 · Berean Standard Bible
Like birds hovering overhead, so the LORD of Hosts will protect Jerusalem. He will shield it and deliver it; He will pass over it and preserve it.”
Context
3Ṣùgbọ́n ènìyàn lásán ni àwọn ará Ejibiti
wọn kì í ṣe Ọlọ́run;
ẹran-ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí.
Nígbà tí Olúwa bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde,
ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọsẹ̀,
ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú;
àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun. 4Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:
“Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í ké
àní kìnnìún ńlá lórí ẹran ọdẹ rẹ̀
bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn
tí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojú rẹ̀,
ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọn
akitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wá
láti jagun lórí òkè Sioni àti lórí ibi gíga rẹ̀. 5Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè
Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bo Jerusalẹmu,
Òun yóò dáàbò bò ó, yóò sì tú u sílẹ̀
Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.” 6Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. 7Nítorí ní ọjọ́ náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò kọ àwọn ère fàdákà àti wúrà tí ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín ti ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.