Isaiah 31:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ènìyàn lásán ni àwọn ará Ejibiti wọn kì í ṣe Ọlọ́run; ẹran-ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí. Nígbà tí Olúwa bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọsẹ̀, ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú; àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun.
Isaiah 31:3 in English
Isaiah 31:3 · Berean Standard Bible
But the Egyptians are men, not God; their horses are flesh, not spirit. When the LORD stretches out His hand, the helper will stumble, and the one he helps will fall; both will perish together.
Context
1Ègbé ni fún àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí
Ejibiti fún ìrànlọ́wọ́,
tí wọn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin
tí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin wọn
àti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn,
ṣùgbọ́n tiwọn kò bojú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli n nì,
tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Olúwa. 2Síbẹ̀síbẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́ ọlọ́gbọ́n ó sì lè mú ìparun wá;
òun kì í kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ.
Òun yóò dìde sí ilé àwọn ìkà,
àti sí àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aṣebi. 3Ṣùgbọ́n ènìyàn lásán ni àwọn ará Ejibiti
wọn kì í ṣe Ọlọ́run;
ẹran-ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí.
Nígbà tí Olúwa bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde,
ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọsẹ̀,
ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú;
àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun. 4Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:
“Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í ké
àní kìnnìún ńlá lórí ẹran ọdẹ rẹ̀
bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn
tí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojú rẹ̀,
ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọn
akitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wá
láti jagun lórí òkè Sioni àti lórí ibi gíga rẹ̀. 5Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè
Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bo Jerusalẹmu,
Òun yóò dáàbò bò ó, yóò sì tú u sílẹ̀
Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.