Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òṣùpá yóò sì tàn bí oòrùn, àti ìtànṣán oòrùn yóò mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po méje, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ odidi ọjọ́ méje, nígbà tí Olúwa yóò di ojú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ tí yóò sì wo ọgbẹ́ tí ó ti dá sí wọn lára sàn.

Isaiah 30:26 in English

Isaiah 30:26 · Berean Standard Bible

The light of the moon will be as bright as the sun, and the light of the sun will be seven times brighter—like the light of seven days—on the day that the LORD binds up the brokenness of His people and heals the wounds He has inflicted.

Context

24Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ń tú ilẹ̀ yóò jẹ oúnjẹ àdídùn tí a fi àmúga àti ṣọ́bìrì fọ́nkálẹ̀. 25Ní ọjọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò sọ ẹ̀mí wọn nù nígbà tí ilé ìṣọ́ yóò wó lulẹ̀, odò omi yóò sàn lórí òkè gíga àti lórí àwọn òkè kékeré. 26Òṣùpá yóò sì tàn bí oòrùn, àti ìtànṣán oòrùn yóò mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po méje, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ odidi ọjọ́ méje, nígbà tí Olúwa yóò di ojú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ tí yóò sì wo ọgbẹ́ tí ó ti dá sí wọn lára sàn. 27Kíyèsi i, orúkọ Olúwa ti òkèèrè wá pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti kurukuru èéfín tí ó nípọn; ètè rẹ̀ kún fún ìbínú ahọ́n rẹ̀ sì jẹ́ iná ajónirun. 28Èémí rẹ̀ sì dàbí òjò alágbára, tí ó rú sókè dé ọ̀run. Ó jọ àwọn orílẹ̀-èdè nínú kọ̀ǹkọ̀sọ̀; ó sì fi sí ìjánu ní àgbọ̀n àwọn ènìyàn láti ṣì wọ́n lọ́nà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.