Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ń tú ilẹ̀ yóò jẹ oúnjẹ àdídùn tí a fi àmúga àti ṣọ́bìrì fọ́nkálẹ̀.

Isaiah 30:24 in English

Isaiah 30:24 · Berean Standard Bible

The oxen and donkeys that work the ground will eat salted fodder, winnowed with shovel and pitchfork.

Context

22Lẹ́yìn náà ni ẹ ó ba àwọn ère yín jẹ́ àwọn tí ẹ fi fàdákà bò àti àwọn ère tí ẹ fi wúrà bò pẹ̀lú, ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí obìnrin fi ṣe nǹkan oṣù ẹ ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kúrò níbí!” 23Òun yóò sì rọ òjò fún un yín sí àwọn irúgbìn tí ẹ gbìn sórí ilẹ̀, oúnjẹ tí yóò ti ilẹ̀ náà wá yóò ní ọ̀rá yóò sì pọ̀. Ní ọjọ́ náà ni àwọn ẹran ọ̀sìn yín yóò máa jẹ koríko ní pápá oko tútù tí ó tẹ́jú. 24Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ń tú ilẹ̀ yóò jẹ oúnjẹ àdídùn tí a fi àmúga àti ṣọ́bìrì fọ́nkálẹ̀. 25Ní ọjọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò sọ ẹ̀mí wọn nù nígbà tí ilé ìṣọ́ yóò wó lulẹ̀, odò omi yóò sàn lórí òkè gíga àti lórí àwọn òkè kékeré. 26Òṣùpá yóò sì tàn bí oòrùn, àti ìtànṣán oòrùn yóò mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po méje, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ odidi ọjọ́ méje, nígbà tí Olúwa yóò di ojú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ tí yóò sì wo ọgbẹ́ tí ó ti dá sí wọn lára sàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.