Isaiah 30:28
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èémí rẹ̀ sì dàbí òjò alágbára, tí ó rú sókè dé ọ̀run. Ó jọ àwọn orílẹ̀-èdè nínú kọ̀ǹkọ̀sọ̀; ó sì fi sí ìjánu ní àgbọ̀n àwọn ènìyàn láti ṣì wọ́n lọ́nà.
Isaiah 30:28 in English
Isaiah 30:28 · Berean Standard Bible
His breath is like a rushing torrent that rises to the neck. He comes to sift the nations in a sieve of destruction; He bridles the jaws of the peoples to lead them astray.
Context
26Òṣùpá yóò sì tàn bí oòrùn, àti ìtànṣán oòrùn yóò mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po méje, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ odidi ọjọ́ méje, nígbà tí Olúwa yóò di ojú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ tí yóò sì wo ọgbẹ́ tí ó ti dá sí wọn lára sàn. 27Kíyèsi i, orúkọ Olúwa ti òkèèrè wá
pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti kurukuru
èéfín tí ó nípọn;
ètè rẹ̀ kún fún ìbínú
ahọ́n rẹ̀ sì jẹ́ iná ajónirun. 28Èémí rẹ̀ sì dàbí òjò alágbára,
tí ó rú sókè dé ọ̀run.
Ó jọ àwọn orílẹ̀-èdè nínú kọ̀ǹkọ̀sọ̀;
ó sì fi sí ìjánu ní àgbọ̀n àwọn ènìyàn
láti ṣì wọ́n lọ́nà. 29Ẹ̀yin ó sì kọrin
gẹ́gẹ́ bí i ti alẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe àjọyọ̀ àpéjọ mímọ́,
ọkàn yín yóò yọ̀
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ènìyàn gòkè lọ pẹ̀lú fèrè
sí orí òkè Olúwa,
àní sí àpáta Israẹli. 30Olúwa yóò jẹ́ kí wọn ó gbọ́ ohùn ògo rẹ̀
yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí apá rẹ̀ tí ó ń bọ̀ wálẹ̀
pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti iná ajónirun,
pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná, àrá àti yìnyín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.