Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin ènìyàn Sioni, tí ń gbé ní Jerusalẹmu, ìwọ kì yóò sọkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn.

Isaiah 30:19 in English

Isaiah 30:19 · Berean Standard Bible

O people in Zion who dwell in Jerusalem, you will weep no more. He will surely be gracious when you cry for help; when He hears, He will answer you.

Context

17Ẹgbẹ̀rún (1,000) yóò sá nípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan; nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn-ún gbogbo yín lẹ ó sálọ, títí a ó fi yín sílẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí igi àsíá ní orí òkè, gẹ́gẹ́ bí àsíá lórí òkè.” 18Síbẹ̀síbẹ̀ Olúwa sì fẹ́ síjú àánú wò ọ́; ó dìde láti ṣàánú fún ọ. Nítorí Olúwa jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é! 19Ẹ̀yin ènìyàn Sioni, tí ń gbé ní Jerusalẹmu, ìwọ kì yóò sọkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn. 20Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò fi ara sin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn. 21Bí o bá yí sápá ọ̀tún tàbí apá òsì, etí rẹ yóò máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, “Ọ̀nà nìyìí, máa rìn nínú rẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.