Isaiah 30:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹgbẹ̀rún (1,000) yóò sá nípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan; nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn-ún gbogbo yín lẹ ó sálọ, títí a ó fi yín sílẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí igi àsíá ní orí òkè, gẹ́gẹ́ bí àsíá lórí òkè.”
Isaiah 30:17 in English
Isaiah 30:17 · Berean Standard Bible
A thousand will flee at the threat of one; at the threat of five you will all flee, until you are left alone like a pole on a mountaintop, like a banner on a hill.
Context
15Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli wí:
“Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà,
ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà,
ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn. 16Ẹ̀yin wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò sálọ lórí ẹṣin.’
Nítorí náà ẹ̀yin yóò sá!
Ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa yóò gun àwọn ẹṣin tí ó yára lọ.’
Nítorí náà àwọn tí ń lé e yín yóò yára! 17Ẹgbẹ̀rún (1,000) yóò sá
nípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan;
nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn-ún
gbogbo yín lẹ ó sálọ,
títí a ó fi yín sílẹ̀
àti gẹ́gẹ́ bí igi àsíá ní orí òkè,
gẹ́gẹ́ bí àsíá lórí òkè.” 18Síbẹ̀síbẹ̀ Olúwa sì fẹ́ síjú àánú wò ọ́;
ó dìde láti ṣàánú fún ọ.
Nítorí Olúwa jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́.
Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é! 19Ẹ̀yin ènìyàn Sioni, tí ń gbé ní Jerusalẹmu, ìwọ kì yóò sọkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.